Sun ọjọ-ori fun ifọwọsi soke ni orilẹ-ede Naijiria

Kudirat Abiola, Temitayo Asuni and Susan Ubogu  | 

(Courtesy of CNN)

(Courtesy of CNN)

Awọn agunbanirọ mẹta n wa bi opin yoo ṣe deba igbeyawo ọmọde ni orilẹ-ede Naijiria nipa kikọ iwe ẹhónú lati paarọ ofin rẹ.

Ni orilẹ-ede Naijiria, ida mẹtalelogoji ninu ọgọrun awọn obinrin l’oti gbeyawo ni ọjọ ibi ọdun mejidinlogun wọn. Ọpọ awọn ọmọbinrin yii ni wọn fi ipa mú kuro ni ile-iwe ati sinu ipò abiyamọ  ki wọn to setan l’ọkan ati l’ara lati ni idile.

Gẹgẹ bi awọn agunbanirọ ọmọ bibi orilẹ-ede Naijiria mẹta, a ri bi igbeyawo ọmọde ṣe n de awọn ẹlẹgbẹ wa lọna lati kun oju osunwọn. Ni osun kejila ọdun 2018, a sẹda ẹgbẹ naa, It’s Never Your Fault, lati fi agbara kun awọn ọmọbinrin ati obinrin ni agbegbe wa ati lati ṣe ipenija fun awọn ijiya aitọ ti wọn dojukọ, pẹlu igbeyawo ọmọde. 

Lẹyin ikẹkọ pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ko l’oye bi igbeyawo ọmọde ṣe lagbara to tabi bi o ṣe n ṣẹlẹ wẹlẹwẹ si, a ṣe afojusun ipa wa lori kikọ awọn ara ilu lori ọrọ yii ati kikọ wọn nipa ayọrisi odi rẹ, pẹlupẹlu pipa ile-iwe ti, iwa aibẹgbẹ pe, arokan, iyẹpẹrẹ ara-ẹni ati ilokulo imọlara, ara ati ọpọlọ. A fẹ ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria mọ pe nigbati awọn ọmọbinrin ba gbeyawo ki wọn to ṣetan, kii se awọn ti ọrọ kan nikan lo pa lara sugbọn gbogbo orilẹ-ede lo n pa lara pẹlu. Igbeyawo ọmọde le fi opin si ẹkọ ọmọbinrin, mu ki aikawe pọ si, o si le mu ifasẹhin ba idagbasoke eto ọrọ aje orilẹ-ede kan . A ṣẹda Instagram ati Twitter nibi ti a ti n kọ awọn ọmọlẹyin lori awọn ipa buburu ti igbeyawo ọmọde a si njẹ ki wọn mọ nipa ipolongo wa loorekoore.

A fẹ ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria mọ pe nigbati awọn ọmọbinrin ba gbeyawo ki wọn to ṣetan, kii se awọn ti ọrọ kan nikan lo pa lara sugbọn gbogbo orilẹ-ede lo n pa lara pẹlu.

Bakanna, a fẹ l’oye ọrọ naa ni ti ilana ofin ki a si wo ohun ti ofin orilẹ-ede Naijiria sọ nipa igbeyawo ọmọde. A ri wipe iwe ofin ọdun 1999 ti orilẹ-ede Naijiria sọ wipe, “Eniyan kan to ba keere si ọdun mejidinlogun ko ni ipa lati ṣe igbeyawo gidi. Ti iru igbeyawo bẹẹ ba waye, o yẹ ki o jẹ fifagile ti ko si ni f’ẹsẹ mulẹ.” Ipin 29(4b) tako iyẹn ni sisọ pe, “Èyi jẹ nipa ipese rẹ pe  obirinkobirin to ba ṣe igbeyawo gbọdọ ti t’oju bọ.” Apa keji yii tumọ si pe ko si bi ọmọbinrin kan tabi obinrin kan sele dagba to, kete tio ba ti ṣe igbeyawo, ofin ti rii bi ẹniti o ti t’oju bọ ti isopọ naa si ba ofin mu.

A sẹda ifẹhónúhàn sun ọjọ-ori fun ifọwọsi soke ni orilẹ-ede Naijiria lati se afiye ipo ti ofin Naijiria wa lori igbeyawo ọmọde. Nipa ifẹhónúhàn naa, a nkesi ijọba lati sun ọjọ-ori ifọwọsi soke ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji ti Naijiria si ọdun mejidinlogun (ki a si rii pe eyi fi ẹsẹ mulẹ!), ati lati ṣe atunṣe ipin 29(4b) ti iwe ofin lati ka wipe, “Ọdọmọbinrin kankan ko leṣe igbeyawo titi yoo fi pe ọdun mejidinlogun.” Lọwọlọwọ, awọn ipinlẹ kan ti fi ofin lọlẹ, bii Iṣe Ẹtọ Ọmode, eyiti o tako igbeyawo saaju ọjọ-ori ọdun mejidinlogun, sugbọn ni ọpọ igba ni awọn osiṣẹ kii fi ipa mu ofin naa ṣẹ nitori awọn isọwọ odi ti iwe-ofin duro le lori ọrọ igbeyawo ọmọde. 

Nigbati a kọkọ bẹrẹ ẹhónún naa, a ni ifọwọsi mẹta pere (ti wa). Sugbọn kete ti ọrọ naa gbalẹ lori ẹrọ ibaraẹnidọrẹ ayelujara, a rii pe ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lo gbaruku ti akitiyan wa. A ri ami ifọwọsi awọn eniyan ẹgbẹrun lọna mẹẹdọgbọn ki o to pe ọsẹ meji! Lọwọlọwọ a ni ami ifọwọsi 236,950 ati pe nọmba naa n gbooro si lojoojumọ. A pète lati lo ẹhónú naa gẹgẹ bi ẹri pe awọn ọmọ Naijiria lọwọ si ayipada lori ipo ofin orilẹ-ede wa lori igbeyawo ọmọde nigbati a ba mu awuyeye wa lọ si iwaju Ile Igbimọ Asofin titi opin ọdun yii.

Lati fi opin si igbeyawo ọmọde, a gbọdọ dojukọ ọrọ naa lọna meji: ki a ṣe atunṣe iwe ofin wa ati ki a paarọ awọn ohun abalaye ati ero ọkan ti o gbaruku ti igbeyawo ọmọde ni orilẹ-ede wa. A nilo ọpọ eniyan lati gbarukuti wa ninu ija yii. O le fọwọsi ẹfihónú han wa ki o si le tẹle wa lori Instagram ati Twitter lati kẹkọ sii nipa igbeyawo ọmọde ni orilẹ-ede Naijiria. 

A fẹ ki gbogbo awọn ọmọbinrin ni orilẹ-ede Naijiria ki o ni anfaani lati kun oju osunwọn, sugbọn wọn ko le ṣe iyẹn ti awujọ wa ba n tẹsiwaju lati fi ipa sọ wọn di iyawo ati iya ki wọn to ṣetan. 

flower.png
Meet the Author
Meet the Author
Kudirat Abiola, Temitayo Asuni and Susan Ubogu

are a group of Nigerian teens working to end child marriage. Kudirat Abiola is a 16-year-old Nigerian student and human rights activist. For her services inside and outside the classroom, she has received numerous awards and honors. Temitayo Asuni is a 16-year-old Nigerian student and recipient of the Oracle Student Recognition Award. She is adept at coding in multiple languages, including HTML, CSS and JavaScript. Susan Ubogu is a self-made entrepreneur and activist. At the age of 17, she owns a mediatech company, Fortunato IX, and has also received numerous awards for her programming and writing talents.