Èrèdí tí mi ò fi níí túmọ̀ àwọn ìtàn àti ìdánimọ̀ mi láti bá àṣà àwọn Òyìnbó mu

Simi Aluko  | 

(Courtesy of Zainub Balla)

(Courtesy of Zainub Balla)

A tọ́ mi dàgbà ní Apapa, erékùsù etí òkun kékeré kan ní Ìlú Eko, olú ilé iṣẹ́ ìṣúná ilẹ̀ Nigeria. Nígbà tí mo ndàgbà sókè, àwọn ọ̀rọ̀ nípa òwò ṣíṣe yí mi ká. Mo máa ntẹ́tí sílẹ̀ sí àwàdà àwọn ọ̀dọ́mọdé olùdáṣẹ́sílẹ̀ ọjọ́ ọ̀la tí --- bí wọn ṣe ma ń sọ ọ́ --- wọ́n pe ara wọn ní onísẹ́ “kárà-kátà.” Èmi náà jẹ́ olùdáṣẹ́sílẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́fà. Ní òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, mo máa nkọ àkójọpọ̀ ìtàn mẹ́rin tí mo sì máa nta awọn ìwé ìtàn naa fún ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ọ́rìn tí ó gba ẹnu ọ̀nà ilé àwọn òbí mi kọjá. Ogbọ́n àtinúdá inú mi ti rọ̀ mọ́ iṣé òwò ṣíṣe nígbà tí ilé mi sì jẹ́ ibùdó kékeré nípasẹ̀ ibi tí mo ń gbà bá gbogbo àgbáyé rìn papọ̀.

Ojúlówó ojúkò ìròyìn àwọn ọmọde ndé sí ọ̀dọ̀ mi ní òwú̀rọ̀ ójoojúmọ́, èyí tí tí ó ngbéni ró, tí ó nfani mọ́ra tí ó sì ndáni lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ètò orí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, ìwé kíkà, orin àti jù bẹ́ẹ̀ lọ yìí ni ó kún fún àwọn òdiwọ̀n ẹwà ilẹ̀ Europe àti òdiwọ̀n làákàyè àwọn Òyìnbó; àwọn ìrètí àti èrò ọkàn tí ó léwu tí mo ń kó kúrò tí mo sì ń yọ kúrò lara awọn ohun tí mo kọ títí di òní. Mo nṣẹ̀dá mo sì nṣe ìfiránṣẹ́ iṣẹ́ ọnà tèmi, ṣùgbọ́n ní ìgbà ọ̀dọ́ yẹn pàápàá, mo ní ìmọ̀lára ohun tí àwọn oníṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Afrika míràn ndojúkọ láti túmọ̀ àwọn ìtàn àti ìdánimọ̀ wa sí àṣà Òyìnbó. Nítorínáà ìwé kíkọ mi tẹ̀lé ìlànà ìṣẹ̀dá àti àyídáyidà tí ó le. Orúkọ ẹni ìtàn: Funke. Ìṣọwọ́ pèdè:Gẹẹsì, Irun: títọ́. Àwọ̀ ara: Funfun. Àtúnṣe orúkọ: Tracy. Ó ti wá ṣetán fún ìfiránṣẹ́.

(Courtesy of Zainub Balla)

(Courtesy of Zainub Balla)

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan tí ooru mú arabinrin mi kan yà sí ilé wa nígbà tí mo nkọ̀wé lọ́wọ́. A sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa iṣẹ́ mi, ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mú ìmọ̀ràn wá pé kí nṣe ìwádìí àwọn litiresọ ilẹ̀ Afrika. Mi ò ronú púpọ̀ nípa rẹ̀ nígbà yẹn, ṣùgbọ́n èrò náà wọnú ọkàn mi lọ fún nnkan tí ó tó ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbòóṣe, ní sáà mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀dọ́mọdé Akẹ́kọ̀ọ́ Yale ti Ilẹ̀ Afrika , mo ní ànfààní láti bá àwọn kan lára àwọn olórí akẹ́kọ̀ọ́ tí ó já fáfá jùlọ ní ilẹ̀ Afrika ní gbólóhùn. Nígbà tí mo nlọ síbi ètò náà mo kọ mo sì pín àròkọ kan tí ó dá lori ojú ìwòye nípa ìdánimọ̀,.Èsì rere kan ntẹ̀lé òmíràn tí ìrírí náà sì ru èmi àti àwọn míràn lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde YYAS sókè láti dá Illino sílẹ̀, àjọ kan tí kò lépa èrè tí ó nṣe ìwúrí fún èrò tuntun iṣẹ́ ọnà èyí tí àṣà nru sókè. Illino ni ibi tí mo ti gbọ̀règẹ̀jigẹ̀ ninu ìlànà bí a tii so ìtàn ati ìṣẹ̀ṣe pọ̀ ninu iṣẹ́ ọ̀na tí a fi ọgbọ́n àtinúdá gbé kalẹ̀ ni ayé òde òní.

Mo nṣẹ̀dá mo sì nṣe ìfiránṣẹ́ iṣẹ́ ọnà tèmi, ṣùgbọ́n ní ìgbà ọ̀dọ́ yẹn pàápàá, mo ní ìmọ̀lára ohun tí àwọn oníṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Afrika míràn ndojúkọ láti túmọ̀ àwọn ìtàn àti ìdánimọ̀ wa sí àṣà Òyìnbó.
— Simi Aluko

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn, mo kọ "Bí Ẹmu Ọ̀pẹ Ti Nkan," èyí tí íṣe eré oníṣe mi ìkẹta. Yàtọ̀ sí èyí tí ó pọ̀jù nínú àwọn iṣẹ́ ìgbà èwe mi, ó jẹ́ ìtàn Yoruba gangan.Ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìfẹ́, ó sì tẹ̀ síwájú sí àlàyé onípele tí ó gbọgbọ́n èyí tí ó nṣe àgbéyẹ̀wò àṣà, ìwà ọmọlúàbí àti ohun tí ìyípadà àti èrò tuntun jẹ́. Sáájú nínú ọdún yìí, mo bá ọgbọ̀n àgbàyanu akẹ́kọ̀ọ́ àti akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣẹ́ ọnà méjì ṣiṣẹ́ láti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àgbéjáde “Bí Ẹmu Ọ̀pẹ Ti Nkan.”

Eré oníse Yoruba, tí ó ti wá di abala kan gbòógì tí a mọ̀ sí eré oníṣe ilẹ̀ Nigeria, jẹ́ àpòpọ̀ tí ó gbọgbọ́n nínú èyí tí a ti rí àlọ́, eré orí ìtàgé, ta-nmọ̀-ọ́, òwe, orin, ijó, ìlù lílù àti ewì.Eré oníṣe nkó ipa pàtàkì nínú àṣà Yoruba, nítorí náà ó ṣe pàtàkì láti lóye ìgbé ayé àti ìrònú Yorùbá láti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé “Bi Ẹmu Ọ̀pẹ Ti Nkan.”Níhín, kíkọ eré yìí dìídì jẹ́ ìlànà ìtúmọ̀ --- tàbí ṣíṣe ìfiránṣẹ́ --- gbogbo àṣà yìí sí èdè orí ìtàgé.

(Courtesy of Zainub Balla)

(Courtesy of Zainub Balla)

Nígbà tí mo bá ndọ́wọ́lé kíkọ irú iṣẹ́ àṣà tàbí ti ìtàn yòówù, mi ò lè sọ bí iṣẹ́ ìwádìí ti ṣe pàtàkì tó. Mo ka iṣẹ́ àwọn onímọ̀ nípa àṣà lórí àwọn obìnrin ṣáájú sáà àwọn Òyìnbó ní ilẹ̀ Yoruba, àgbékalẹ̀ ìjọba ti ìbílẹ̀, àwọn ìlànà fífún ọba ládé, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn abala àṣà míràn. Kí ntó kọ ìlà àkọ́kọ́ ti “Bí Ẹmu Ọ̀pẹ Ti Nkan,” mo ti lo ọdún méjì ní bònkẹ́lẹ́ tí mo nká nípa àṣà Yoruba --- ní pàtàkì jùlọ nítorí iṣẹ́ mi pẹ̀lú Illino --- àti àwọn odindi ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí mo nṣe iṣẹ́ ìwádìí fún eré náà fúnraarẹ̀.

Iṣẹ́ ìwádìí náà dìídì wà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ --- ònkọ̀wé náà --- ri ara rẹ bọnú ìgbé ayé tí o ngbìyànjú láti gbé kalẹ̀ náà. Àwọn ohun tí o kọ́ nípa rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí ó gbé ìtàn rẹ dúró, kìí ṣe àṣeparí rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ gbọ́dọ̀ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ojúlówó ìgbé ayé kan tí o ní láti mọ̀ dáradára. O gbọ́dọ̀ lóye ìgbé aye ojoojúmọ́, àwọn ìṣúná, ètò iṣẹ́, ẹ̀sìn, èèwọ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ́ pé àwọn ìrònú, ìpinnu àti ìtàkúrọ̀sọ àwọn ẹni ìtàn rẹ̀ yóò wá láti ìhín. Nígbà tí o bá ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí ṣíṣe àgbékalẹ̀ ìgbé ayé yìí, nígbà náà ni o ó rékọjá sí ṣíṣe àgbékalẹ̀ ẹni ìtàn àti ìpele.Tí o bá nṣe é dáradára, kò níí ká ọ mọ́ ṣùgbọ́n yóò ṣí àwọn ilẹ̀kùn tuntun, àwọn ọ̀rọ̀ tuntun, àríyànjiyàn tuntun àti àwọn èrò inú tuntun. Ìlànà yìí ni ìyàtọ̀ gbòógì láárín ṣíṣe ẹ̀dá àlàyé ilẹ̀ Afrika àti àlàyé aládùn ilẹ̀ Afrika.

Iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Afrika ni a sábà máa ngbé jáde tí a sì nfi ránṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu bí àwọn olùgbọ́ tí kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Afrika ti fẹ́ ẹ; ní àwọn àkókò bí èyí, iṣẹ́ ọnà wa kìí ṣojú wa ní kíkún, ṣùgbọ́n èyí tí àwọn tí ó nra ọja wa bá fẹ́ nìkan.
— Simi Aluko

Ìyàtọ̀ gbòógì míràn ni ti yíyàn àwọn tí yóò gbọ́ ọ. Nígbà ìwé kíkọ náà, mo ní àwọn ìtàkúrọ̀sọ díẹ̀ tí kò parí pẹ̀lú ọ̀jọ̀gbọ́n ònkọ̀wé eré oníṣe mi, Joe Martin. Ní ọjọ́ kan ní àkókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa, ó tọ́ka sí àwọn awẹ́ gbólóhùn díẹ̀ tí yóò máa dà rú mọ́ olùgbọ́ ilè Amẹrika lójú. Mo pinnu mo sì kéde pé eré náà wà fún olùgbọ́ ilẹ̀ Nigeria. Ọ̀jọ̀gbọ́n mi gbà ó sì ṣe àtìlẹ́yìn fún u, ìyẹn sì nìyẹn. Iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Afrika ni a sábà máa ngbé jáde tí a sì nfi ránṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu bí àwọn olùgbọ́ tí kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Afrika ti fẹ́ ẹ; ní àwọn àkókò bí èyí, iṣẹ́ ọnà wa kìí ṣojú wa ní kíkún, ṣùgbọ́n èyí tí àwọn tí ó nra ọja wa bá fẹ́ nìkan. Ṣùgbọ́n nítòótọ́, àṣà kìí ṣe àjọsọ okòwò.

Ní tèmi, àwọn ìtàn tí ó dára jùlọ ni àwọn tí ó jẹ́ òtítọ́ jùlọ. “Bí Ẹmu Ọ̀pẹ Ti Nkan” kọ́ mi pé iṣẹ́ okòwò iṣẹ́ ọnà dìídì wà fún ṣíṣe ẹ̀dá àwọn ìwádìí nípa ìgbé ayé tí ó sopọ̀ mọ́ ara wọn, tí ó ní àròjinlẹ̀, tí ó jẹ́ òtítọ́. Gẹ́gẹ́ bí olùpìtàn a sábà máa nsọ fún wa láti kọ àwọn ìtàn tí yóò tà, bákan náà, a tún maa ń sọ fún wa pé pé a jẹ́ eni tí kò dúró lójú kan, tí kò wuni tí kò sì wuyì. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn tí a fi iná sun ìdánimọ̀ wa nínú oko àwa fúnra wa, a gbìn í gẹ́gẹ́ bí irè oko tí ó nmówó wá jùlọ ní ibòmíràn. Ìwà yíyí àwọn ìtàn padà sí ohun tí àwọn oníbàárà nfẹ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ti kùnà gidigidi; bíbuyì kúnni nípasẹ̀ iṣẹ́ ọnà wa ni ó yẹ kí àfojúsùn wa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Eazi ti sọ nígbà kan rí, “Níbi tí ìdíyelé bá wà, ìgbà gbogbo ni èrè yóò wà níbẹ̀.”

flower.png
Meet the Author
Meet the Author
Simi Aluko

is a storyteller from Lagos, Nigeria who is passionate about the relationship between culturally-inspired innovation and community development in Africa. She is the founder of Illino, an organisation that produces literary work to preserve and celebrate Nigerian culture. You can follow her on Instagram and Twitter.